
Alade Obafemi
@aladeobafemi
1 year ago
GÌRÌWÒ
Èèmò nbe ní Àkérun,
Kòròrò tí n je obì nbe ní gbònbò Òsíta.
Bí bòògún ò jé,
Bí bòòsà ò tà;
Bí gigun ò bó,
Bí tòkè ò kúrò níginmú Àrímú.
Ní àhín nìtìjú ti dààre,
Imí ò sì pohùnrere Elégbin.
Èjè n tutù ìfé,
Ògòrò n pègàn òtító;
Ah! Ìsimi dà fún Àlejò ara?
Alára tí n fàrán dárà àjetútú; asán.
Àsán lòsán Agbósán sasán,
Gìrìwò rè é! Má jà sófìn.
© Alade Obafemi Babafemi
