
Alade Obafemi
@aladeobafemi
1 year ago
ADÌGÚN
Onídùrù, ojúkejì Onítara;
Èta okùn fohùn òtító,
Pé bínú n seré, bé è lokùn ó tàn.
Àtòhúnwá lelétí yára fèsì,
Pé ní tijó, ún ò bùn ó lésè;
Ní tokàn, ún ò bùn ó lóyàyà;
Èrín èké mi ó dìjo so àsírí dídún owó.
Bí Eléré, mo tóka sí gbàgede;
Bí Aláyò, mo tàn dórun,
Bí Olólùfé, mo n koná aráyá.
Bé è sì ni àyò mi ò gbodò ní ònkà méjì.
© Alade Obafemi Babafemi
